Lẹ́yìn aṣọ ìkélé àwùjọ Nàìjíríà, ọ̀rọ̀ nìì “Asháwó” ń ta okùn ìtàn òun àrọ́bá líle, èyí tí ó ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀tanú àti ìfaradà. Àfi bí ipa ohun èlò ìkuǹkan lára ìgbòkun, ọ̀rọ̀ náà ń kun àwòrán àwọn ìdojúkọ tí àwọn obìnrin Nàìjíríà ń kojú ní ilé ayé tí ń ṣe ègbè lẹ́hìn ọkùnrin. Àfihàn wa, tí ń jẹ́ Asháwó: ta ló sọ wípé alágbèrè ni ẹ́?? ń pè yín láti wá rẹ ara yín lómi nínú ìfọ̀ rọ̀ wérọ̀ oníṣẹ́ ọnà tí yóò máa wáyé láàárín àwọn olúdá iṣẹ́ ọnà mẹ́rin; àwọn ọ̀dọ́bìnrin oníṣẹ́ ọnà mẹ́ta láti inú ìgboro oní pọ̀ pọ̀ sìnsìn ti ìlú Èkó, àti ẹnìkan láti olú ìlú, Àbújá.

Nípa parápọ̀ iṣẹ́ ọnà àwòrán, ìfihàn nípa aṣọ àti ìjẹmọ́ aṣọ, fọ́nrán ìtàn ìpamọ́ tí ó jingíro àti ìṣe ìtàgé ọlọ́ kan-ò-jọ̀ kan tí yóò mú ìmọ̀ lára wáyé, àwọn ohùn yìí kojú kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣesí àwùjọ.

Oluwabukunmi Olukitibi, LET ME BreathE h(W)OoMAN, 2024, Audio, text, visual art, picture and videos, performance

JẸ KÍ N MÍ Obìn(Ọkùn)rin)
Èyí ni àfihàn iṣẹ́ Olúwabùkúnmi, tí àkọlé rẹ ń jẹ́ JẸ́ KÍ N MÍ Obìn(Ọkùn)rin, níbi tí ìṣẹ̀dá obìnrin ti dúró ní ojú ìtàgé tó ní ṣe pẹ̀lú ìbámu orin àjídùn tí ń ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iyè inú àti ètò ìfagbárafúnni. Olúwabùkúnmi Olúkìtìbí jẹ́ oníṣẹ́ ọnà orí ìtàgé, olùkópa agbègbè, olùkọ́ ìjo àti yógà pẹ̀ lú pẹ̀ lú oníjó sẹ́lẹ́ńsẹ́ oní-tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé láti Àbújà, Nàìjíríà.

Nípa lílo ìṣípòpadà ara gẹ́gẹ́ bí ipa, ìṣe Olúwabùkúnmi dúró gẹ́gẹ́ bí ìwé àkọsílẹ̀ aláwòrán tí ń tọpa rírì ayé àti ipò rẹ̀ nínú ayé lórí pápá àkókò tí kò ní òpin. Ó ń lo àwọn ìṣe ìtàgé rẹ gẹ́gẹ́bí ọkọ̀ láti fi ìdí ìlànà ìwáṣẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ti ìgbàlódé nípa àwòrán, láì pa rírì ìlànà náà rẹ́.

Nípa iṣẹ́ ọnà JẸ KÍ N MÍ Obìn(Ọkùn)rin, ìlànà onírúurú Olúwabùkúnmi ń ṣe àkànpọ̀ àwòrán, fọ́nrán, ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀, ohùn afètígbọ́ àti ìṣípòpadà ara láti bí ìrírí tí ó ṣe dédé akínyẹmí wíwà gẹ́gẹ́bí obìnrin. Nípa ìwògbé ẹ̀rọ ayàwòrán rẹ, ó tọpinpin ìmọ̀ ìfẹ́ awọ ara àti ìrísí ìbálópọ̀, pẹ̀lú gbígba ẹ̀rí ìmísí lọ́nà tímọ́tímọ́. Láti ìjẹ́wọ̀ olófèé sí ìkéde pẹ̀lú àyà gbàngbà, àwọn ẹ̀yà fọ́nrán rẹ ń pe àwọn òǹworan láti bọ́ ara sí pàtàkì ìfẹ́ obìnrin, wíwó àwọn ìdènà gbogbo àti títú àwọn kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó kọjá èèwọ̀ síta.

Nínú ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀, ó gbé iná wo ojú ẹ̀tanú àwùjọ, ó sì dojúkọ èdè ìmúnisìn àti àtúnsọ ìtàn ìrírí obìnrin. Àwọn àfojúsùn tí ó pọnmi èròńgbà àti ẹ̀rí ìgboyà ló dúró gẹ́gẹ́ bí igbe ìsọ̀ kan fún ìyípadà, nípa wíwú àwọn òǹworan lórí láti da ìbéèrè bo ẹ̀tanú àtinúdá, kí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ìgbé ayé tí ó kó ẹni gbogbo mọ́ra.

Elfrida Grey, Hope in Choas, 2024, Video, 10 min.

Ní ìlànà àfetígbọ́, àkójọpọ̀ ohùn so papọ̀ láti jẹ orin àjídùn ìsọ̀ kan, yínyín sókè àwọn ìtàn àti ìwòye àwọn obìnrin níbi gbogbo. Nípa ìṣe ọ̀nà ọ̀rọ̀ sísọ, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu tímọ́tímọ́ àti ohùn ilẹ̀ tí ń tukọ̀ ìmọ̀lára, ó ń gbìyànjú láti ṣe ìgbèrú àánú ara àti ìgbọ́raẹniyé, èyí tí yóò bí ìwọ́de ìfagbárafúnni àti ìdáǹdè. Ní àkótán, Olúwabùkúnmi Olúkìtìbí fi ẹnu àrà gúnlẹ̀ sí ìṣe ọnà ìtàgé oníṣípòpadà tí ó dá lórí okun, ìfẹ́ ara àti ìfaradà obìnrin. Pẹ̀lú gbogbo ìṣesí fanda fanda àti ìdúró ṣinṣin tó lágbára, oníṣẹ́ ọnà náà gba àkóso lórí ara wọn, ó sì gbé iná wojú ìrètí àwùjọ, nípa líla ọ̀nà fún ọjọ́ ọ̀la tí obìnrin gbogbo ní òmìnira láti gbe oun rere ṣe.

KÍNI O LÈ RÍ?ARA TÀBÍ IRIN IṢẸ ?

“Mo gbà láti jẹ olùkópa nínú àfihàn yìí nítorí mo fẹ́ fi àwọn ìrírí síta, àwọn èyí tí kò ṣe àjòjì ní agbègbè mi nípa bí mo ṣe ti gba oríṣiríṣi àkọlé gẹ́gẹ́bí obìnrin nítorí pé mo wà, mò ń gbé ní ìlòdì sí àṣà ìgbà, mo ní ọkàn tèmi, pẹ̀lú àwọn ìlàkàkà tí àwọn obìnrin mìíràn pẹ̀lú àìlera ń là kọjá ni àwùjọ” - Janet Adéníkẹ́ Adébáyọ̀.

Ní orílẹ̀ ayé tí àwọn ènìyàn ń wulẹ̀ bu obìnrin kù gẹ́gẹ́bí àwọn ohùn aláìlẹ́ẹ̀mí ìfẹ́ ara, kini o lè rí? Ara tàbí irin iṣẹ́? Láti ọwọ́ Janet Adéníkẹ́ Adébáyọ̀ ń pè wá ní jà láti rí àwọn obìnrin gẹ́gẹ́bí ènìyàn, tí oníkálukú sì ní iyì tiẹ̀ àti ìmúṣinṣin tí o kọjá ohun àfojúrí lásán. Nípa onírúurú àkànpọ̀ ìrònú tí ó ń gbé’ni nínú, àfihàn yìí ń pe àwọn òǹworan láti da ìrísí obìnrin wọn ro lórí wíwà lábo àti ìyàtọ̀ takọtabo. Nípa ṣíṣe agbẹnusọ fún dídáwà obìnrin ni ibi iṣẹ́ láti ṣe àtúngbà ibùdó gbangba láì sí ìbẹ̀rù, àwọn iṣẹ́ ọnà yìí ń ké ìpè léraléra fún ìfagbárafúnni àti àpọ́nlé.

Janet Adenike Adebayo, Platonic, 2024, Acrylic on canvas, 36 in x 48 in

Nínú àwùjọ tí àìdáàbòbò àti àmì ìṣàbùkù gbogbo gbòò ti mulẹ̀, oníṣẹ́ ọnà yìí ń gbèrò láti ṣe àmúpadà ìbáṣepọ̀ aláìníkọ́núukọ́ họ àti àjọṣepọ̀ tòótọ́ láàrin takọtabo. Nípa ìparun àmì àbùkù tí ó yí ìbáṣepọ̀ takọtabo ká, ìtàn náà yóò yí sí èyí tí ó mú àgbọ́yé àti ìgbárùkùtì lọ́wọ́. Síbẹ̀ náà, ìrántí ìnira tí àwọn obìnrin, pàápàá àwọn tí ó ní àìlera ń kojú dúró ṣinṣin. Láti àwọn ìlàkàkà abẹ́nú tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìlera ìbímọ títí dé ìtọpinpin àìtọ́ àwọn ìpinnu ìgbà pípẹ́, àfihàn náà ń tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn ohun tí ó ta kókó nípa ìgbésí ayé obìnrin, tí àwùjọ ń fi ojú fò. Nípa àwọn ìrírí tí ó jẹyọ nígbà tí oníṣẹ́ ọnà náà ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn agbẹ̀bí, ó ń pè wá láti gbé iná wojú àwọn àìṣòdodo wa, kí á sì fi àyè gba ìríjú aláàánú lọ́tun. Kíni o lè rí? Ara tàbí irin iṣẹ́? kọjá ohun ìmúdárà lásán, ó ń ṣe ìfúnni ìríjú kàbìtì lórí ìjíròrò takọtabo, ìdánimọ̀ àti ìrètí àwùjọ. Janet Adéníkẹ́ Adébáyò ń sábà máa ń pe ara rẹ̀ ní oníṣẹ́ ọnà ìjẹ́wọ́, tí àwọn iṣẹ́ òun sì ń ṣe àkànpọ̀ àwọn ìjíròrò àwárí ara ẹni àti ìwàláàyè léraléra. Oníṣẹ́ ọnà náà ń fi ọ̀rọ̀ han nípa lílo ọ̀dà àkírílíkì àti àpòpọ̀ èlò lórí ìkùngbo, èlò ìlànà ìṣe, bíi ìbuwọ́ lù oní mòsáíkì aláwọ ara rẹ, àkójọpọ̀ àwọ̀ láti ṣẹ̀dá èrejọni tí ó ní àwọn ẹ̀yà ara mérìírí.

LÁTI ÀPÓTÍ AṢỌ TI ẸYẸ OLỌ TẸ DÚDÚ.
Bíẹṣeńkoibiìṣàfihaniṣẹ́ ọnàwalọ,ẹjẹ́ kín ṣe atọ́nà yín sí onírúurú, alárà gbẹdẹkẹmu wíwà lóbìnrin tí ó di mímọ̀ nínú iṣẹ́ Blessing Offiong Ekpenyong, tí àkọlé rẹ ń jẹ́ láti àpótí aṣọ ti ẹyẹ ọlọ́ tẹ̀ dúdú.

Blessing Offiong Ekpenyong, From the wardrobe of a rebellious blackbird, 2024,Outfits, pictures, video

Àwọn àfihàn Blessing Offiong Ekpenyong wà gẹ́gẹ́ bí ayẹyẹ fún oun ọ̀ tọ̀ọ̀ tọ̀ àti ìkópa gbogbo, ìkómọ́ra ẹwà ara gbogbo àti ẹ̀yà. Pẹ̀lú àkíyèsí rẹ̀ sí oun ìfarapẹ́ àti ọ̀nà ọ̀tun sí ẹ̀wù, àwọn ìṣẹ̀dá oníṣe oge náà bí aṣọ tí ó wà gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣọ́ ara àti ìfọhùn iṣẹ́ ọnà.

Ní àkọ́kọ́, àfihàn “Òrìsà”, èyí tí ó jingirí, tí ó sì jẹ ìfojúsùn àlà, ìgboyà àti mímọ́. Nínú èyí, oníṣẹ́ ọnà náà sọ rírì obìnrin di mímọ̀, láì sí ìfàyègbà ìdájọ́ àwùjọ, èyí tí ó wọ aṣọ àtọ̀runwá, ẹ̀rí ore ọ̀fẹ́ àti ọlá ńlá.

Èyí tí ó kàn ní alábapàdé “Ẹwù ìlékè. B.B”, àfihàn ìfaradà nínú làálàá. Nípa bíbò láti orí dé ọmọ ìka ẹsẹ̀, isẹ́ ọnà náà wà gẹ́gẹ́ bí ìtọpinpin òǹworan, nípa yíyẹ àwọn ìdájọ́ tí kò ní ẹsẹ̀ nílẹ̀ pẹ̀lú ìmúṣinṣin tí ó múná dóko. Kí á tún gbéra lọ si àgbàlá ojúlówó pẹ̀lú “Rúkì”, ibùdó tí òmìnira àti ìdára ẹni lójú tí jọba. Láì fi àkọlé àti ẹ̀sùn àwùjọ ṣe, isẹ́ ọnà yìí ń fi àmì ojúlówó hàn, láì gba ìdènà ìbámu láyè. Nínú “Ọ̀ gábìnrin”, ẹ ṣe àwárí àpapọ̀ ìmọ̀ àti dángájíá, bí ó ń ṣe ń tukọ̀ ayé oníṣẹ́ bí-o-jí o-jí-mi lọ. Pẹ̀lú gbogbo àṣeyọrí obìnrin, ó tún jẹ ẹ̀gbin ẹnu àtẹ́ àìtọ́, ìwògbé àwọn ìṣòro tí obìnrin ń faradà ní ibùdó tí ọkùnrin ń ti ṣe adarí. Ṣe alábapàdé ìtura nínú “Ẹ̀wù ìlékè rẹ́gí”, níbi tí ìmọ̀ ara ẹni àti omi àánú ti pàdé. Láàrin rògbòdìyàn ìrètí àwùjọ, isẹ́ ọnà yìí ń fi ibi mímọ́ fún ni, láti ran àwọn obìnrin létí okun àtinúdá àti ẹwà wọn. Ní àkótán, ṣe ìjúbà fún “Anansà”, àkójọpọ̀ àṣà àti ayẹyẹ. Láì fi ti ìwàrí tí ń gbà, ó tún kojú ìtọpinpin àti àìgbọ́raẹniyé, àwọn orò rẹ sì ń di nkan mìíràn fún àwọn elérò kúkurú. Nínú àfihàn yìí, Ekpenyong ń pè yín láti wá ní ìpàdé pẹ̀lú àwọn ìtakókó wíwà lóbìnrin, pẹ̀lú iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ ẹ̀rí ìfaradà, ojúlówó àti ẹwà obìnrin láì fi ìrètí àti ìdájọ́ àwùjọ ṣe.

ÌRÈTÍ NÍNÚ RÒGBÒDÌYÀN.
Elfrida Grey jẹ́ olùdarí ìṣípòpadà àti ijó sẹ́ lẹ́ńsẹ́ oní- tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé tí ó ní ẹ̀bùn púpọ̀. Àwọn iṣẹ́ ọnà Grey n tọpinpin ìfẹ́ ara, ìjàngbara obìnrin, ìtàn sísọ àti wíwà lóbìnrin. Gbáradì fún ìrírí ìmúṣinṣin tí ń kojú àṣà àwùjọ, tí ń sì ń ṣe ayẹyẹ àdììtú wíwà lóbìnrin.

Elfrida Grey, Hope in Choas, 2024, Video, 10 min.

Nínú iṣẹ́ ọnà Grey, ẹ o rí àtòpọ̀ ijó sẹ́lẹ́ńsẹ́ oní- tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé àti ìtàn sísọ tí ń pe ìmọ̀lára jáde, tí ń sì dá lórí ìrírí onírúurú àwọn obìnrin. Nípa lílo ìlànà ijó ìgbàlódé àti ìgbà pípẹ́, Elfrida Grey ń ṣẹ́ dà àwọn ìṣe ìtàgé tí ó múná dóko, tí ó sì fà yín wọ ìsánlú ayé ìṣe ọnà rẹ. Nínú ọkàn àfihàn wa ni iṣẹ́ alágbára nìì tí Grey ṣẹ́dà, Ìrètí Nínú Rògbòdìyàn. Fọ́nrán àkọsílẹ̀ ìpamọ́ lórí ijó tí ó dá lé àwọn alágbára oníjóbìnrin tí n já ara wọn gbà nínú bùkátà àwùjọ àti àmì àbùkù. Ṣé alábapàdé ijó sẹ́lẹ́ńsẹ́ oní-tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé dídùn yìí bí àwọn oníjó, tí ó wọ aṣọ funfun àmútọ̀runwá, ṣe ń ṣípò padà ní ìsúnkì amúnimúyè yíká sí ẹ̀rọ orin tí ń jáni lára jẹ, tí wọ́n sì ń fara sin àwọn ìlàkàkà ojúmọ́ gbogbo tí àwọn obìnrin ń kọjú, pàápàá lórí àbùkù àwùjọ.

Ní òpin ohun gbogbo, àfihàn yìí kúrò ní ìpàdé iṣẹ́ ọnà lásán: ìpè sí ìṣe lọ́gán ni, àyájọ́ fún àyípadà. Pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àwọn oníṣẹ́ ọnà obìnrin yìí ń pè wá láti tún ìtàn kọ, pẹ̀lú lílo ohun èlò tó yẹ ní sísẹ̀ ń tẹ̀lé, títí tí yóò fi ṣe àfihàn ayé tí gbogbo obìnrin tiwàgẹ́gẹ́bíẹniàńṣeayẹyẹfún,àńpọ́nlé,tíósì ni òmìnira láti fò kọjá ọ̀run tantan. Ìforíkorí sí orin ìṣọ̀kan, ìṣẹ̀dá ọjọ́ ọ̀la tí ohùn léraléra “Asháwó” yóò parẹ́ nínú ìtàn, tí yóò sì di rírọ́pò pẹ̀lú àpètúnpè ìfagbárafúnni àti dídọgba.

Amaechina David SNIPES
Open Call Exhibition
© apexart 2024

To the exhibition page